Koronafairọsi jẹ́ ẹbí ńlá ti kòkòrò kan èyítí a mọ̀ pé ń ṣokùnfà àìsan láti otútù tó wọ́pọ̀ sí àwọn àrùn tó lágbára bíi Àrùn Mímí Middle East (MERS) àti Àrùn Mímí Tó Lágbára (SARS).
Gbajúgbajà koronafairọsi (COVID-19) kan ní a rí ní ọdún 2019 ní Wuhan, China. Èyí jẹ́ koronafairọsi titun kan èyítí a kò rí tẹ́lẹ̀ láàrín ọmọnìyàn.
Ẹ̀kọ́ yìí ń pèsè àfihàn gbogbogbò sí COVID-19 àti àwọn kòkòrò mímí tí ń jẹyọ a sì ṣeé fún àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ìlera gbogbo ènìyàn, àwọn adarí ìṣẹ̀lẹ̀ àti àwọn òṣìṣẹ́ tí ń ṣiṣẹ́ fún United Nations, àwọn àjọ àgbáyé àti àwọn NGO.
A fún àrùn yìí ní orúkọ gbogbogbò lẹ́yìn tí a ṣẹ̀dá ohun èlò, bí a dá dárúkọ nCoV èyí túmọ̀ sí COVID-19, àrùn àkóràn èyití koronafairọsi tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàwárí ṣokùnfà.
Jọwọ ṣe akiyesi pe akoonu ti iṣẹ-ẹkọ yii ti wa ni atunyẹwo lọwọlọwọ lati ṣe afihan itọsọna to ṣẹṣẹ julọ. O le wa alaye imudojuiwọn lori awọn koko-ọrọ ti o jọmọ COVID-19 ninu awọn iṣẹ ikẹkọ atẹle:
Ajẹsara: ikanni awọn ajesara COVID-19
Awọn iwọn IPC: IPC fun COVID-19
Idanwo aisan ti o ni kiakia Antigen: 1) SARS-CoV-2 antijeni ti o ni kiakia idanwo aisan; 2) Awọn imọran pataki fun imuse SARS-CoV-2 antigen RDT